Islam woye si iba ara-eni-lopo (laarin okunrin ati obinrin) gegebi oun Pataki ti sise re je oranyan, koda o tun je oun ti esin ni ife si, nigba ti a ba se ni ibamu si ilana ti olohun. Ko si ninu oun egbin ti omoniyan gbodo korira re. Olohun sope: ''Won ti se ni oso fun omoniya ojukokoro lara awon; obinrin, omo, dukia ti o po, wura ati adaka, esin ti o rewa, awon oun osin ati ile-oko ti o dara, eleyi je oun igbadun aye, sugbon odo olohun ni abo daadaa wa'' Q3:14.